Hymn 44
Mo wa ninu emi li ojo Oluwa.
Meter: 7.6.7.D.
Scripture: Ifi. 1:10
1
fOjo ‘simi at’ayo
Ojo inu didun,
Itunu fun ‘banuje
Ojo dida julo,
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re,
PNko Mimo, Mimo, Mimo,
S’Eni Metalokan.
2
fL’ojo yi n’imole la,
Nigba dida aye,
Ati fun igbala wa,
Krist’ jinde n’nu oku
MfL’ojo yi li Oluwa
Kan Emi t’orun wa,
Ojo Ologo julo
T’a tan ‘mole pipe
3
mfEbute abo ni O
Larin iji aye;
Ogba didara ni O
Nib’omi iye nsan
Orisun ‘tura ni O
Laye aginju yi;
L’ori re, bi ni pisga
L’a nwo ‘le ileri.
4
mpL’oni s’ilu t’ara nu
Ni manna t’orun nbo
Si ipejopo mimo
N’ipe fadaka ndun,
N’ibiti ihinrere
Ntan imole mimo
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.
5
k’a r’ore-ofe titun
L’ojo ‘simi wa yi
K’a si de ‘simi t’o ku
F’awon alabukun,
Nie k’a gbo ‘hun soke
Si Baba at’Omo;
Ati si Emi Mimo
N’iyin Metalokan.