Hymn 440
A wa ti ri irawo re ni iha ila-orun.
Meter: S.M.
Scripture: Mat. 2:2
1
fIrawo wo l’eyi?
Wo b’o ti dara to,
Amona awon keferi
S’odo Oba ogo.
2
Wo awon amoye
Ti ila orun wa;
Won wa fi ori bale fun
Jesu Olubukun.
3
Imole ti Emi,
pMa sai tan n’ilu wa;
Fi ona han wa k’a le lo,
Imanueli wa.
4
fGbogbo irun-male,
Ati igba-male,
Ti a mbo n’ile keferi,
K’o yago fun Jesu.
5
mfKi gbogbo abore
Ti mbe ni Afrika,
Je amoye li otito,
Ki won gb’ebo Jesu.
6
Baba Eleda wa,
Ti O fi Jesu han
Awon keferi igbani;
Fi han fun wa pelu.