Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 442

Nigbati oko iyawo pe, gbogbo nwon to gbe, nwon si sun.

Meter: 7s. 6s. D

Scripture: Mat .25:5

1

mfOluwa y’oti peto,

Ti ’WO o tun pada;

Are fere mu wa tan,

Bi a ti nw’ona Re;

Oluwa y’oti peto

Ta o ma reti Re?

Opo ni ko gbagbo mo

Pe ‘Wo o tun pada.

2

Oluwa y’o ti pe to

Ti 'Wo o kesi wa!

Ti awa ti nreti Re

Yio ri O l’ayo

Ji, wundia ti o sun

Lo kede bibo Re

Ki gbogbo awon t’o sun

Le mo pe O mbo wa

3

fDide, tan fitila re

Gbe ewu mimo wo,

Mura lati pade Re

‘Tori On fere de

Oluwa y’o ti pe to

Ti ’Wo o tun pada?

Ma je ki are mu wa

Tit’ ao fi ri O.