Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 445

Beli awa, eniyan Re ati agutan papa Re yio mafi ope fun O lailai, awa o ma fi iyin Re han lati irandiran.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: OD. 79:13

1

fOorun igbala wa,

Emi at’iye wa,

Ilera at’abo wa,

At’ alafia wa;

Awa omo Re duro

Lati f’iyin fun O

Fun ebun nla t’O fun wa

Ninu Kristi Jesu.

2

Okan wa kun fun ope

Fun ’toju ’gbagbogbo

L’ori awon omo Re

Ni gbogbo agbaye.

mfAwa mbe O jek’awa

Le duro n’nu’fe Re;

fK’imole wa le ma tan

Yi gbogbo aye ka.

3

ffOgo f’Olorun Baba,

At’ Olorun Omo,

Pelu Olorun Emi,

Metalokan laelae;

Jo gba orin iyin wa

Ati adura wa

Fun ebun nla t’O fun wa

Ninu Kristi Jesu.