Hymn 446
E lo, e ma ko orile-ede gbogbo.
Meter: L.M.
Scripture: Mat. 28:19
1
fLo wasu ihinrere Mi
Mu gbogbo aye gb’ore Mi;
Eni t’o gb’oro Mi y’o la,
Eni t’o koo yio segbe.
2
Emi o f’oye nla han yin,
E o f’oro oto Mi han;
Ni gbogbo ise ti Mo se,
Ni gbogbo ise t’e o se.
3
LO WO arun, lo j’oku nde,
F’oruko Mi l’esu jade;
Ki woli Mi mase beru,
Bi Griki ati Ju kegan.
4
Ko gbogbo aye l’ase Mi,
Mo wa lehin yin de opin;
Lowo Mi ni gbogbo ipa,
Mo le pa, mo si le gbala.
5
Imole si ran yi i ka,
Ogo nla l’o fi lo s’orun;
Won si mu de ile jijin,
Ihin igoke Olorun.