Hymn 447
Ibi okunkun aiye, o kun fun ibugbe ika.
Meter: 8s. 7s.
Scripture: OD. 74:20
1
mfE fi oju iyonu wo
Okun ile keferi:
Sa wo bi opolopo won
Ti njowere ’nu ese,
pOkunkun bo, Okunkun bo,
Oju ile aye wa.
2
Imole eni okunkun,
Dide, mu ibukun wa
Imole fawon keferi,
Wa, pelu ’mularada;
Ki gbogb’Oba ki gbogb’Oba
Wa sinu imole na.
3
Je k’awon keferi ti mbo
Igi ati okuta
Wa lati Fi ori bale
Fun Olorun alaaye
Jek’ogo Re, jek’ogo Re,
Bo gbogbo ile aye
4
fIWO t’a fi’pa gbogbo fun,
Soro na! pa ase Re;
Jeki egbe Oniwasu
Tan ’ruko Re ka kiri:
Wa pelu won, Wa pelu won
Oluwa titi d’opin.