Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 45

Nitori omo eniyan je Oluwa ojo isimi.

Meter: L.M

Scripture: Mat. 12:8

1

fOluwa ojo Isimi

Gbo eje wa nihin, loni,

Gba orin iyin ti a nko

Be ebo ope wa si O

2

A fe isimi t’aye yi

Sugbon ‘simi t’orun dun ju;

Eyi ni l’okan wa nle pa;

Pelu itara on ife.

3

mfKo saare mo tab’iponju

Ese tab’egbe kio de ‘be;

Ose ki y’o dapo merin

Ti awon eni aiku nko

4

ko si idagiri ota,

Beni ko s’ipaya nibe;

Ko si oru, ko s’ikuku;

MfAfi osan titi lae lae.

5

Bere, Ojo t’a ti nreti,

Afemoju re l’a fe ri,

A fe yo! Lona ise yi

K’a si de ibi ‘simi na.