Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 450

Ma wi Oluwa, nitori iranse Re ngbo.

Meter: 8.7.8.7.7.7.

Scripture: I Sam. 3:9

1

Ma wi, ’tori ’ranse Re gbo,

Mo duro de oro Re;

Mo fe gb’ohun iwosan Re;

Je k’emi gbo, Oluwa,

Kristi, mo t’eti sile

S’ohun t’O fe wi fun mi.

2

Ma wi, pe mi, Oluwa mi,

Je ki nle mo ohun Re:

Ma wi, ki nyara te le O,

Kin sun mo O girigiri

Nibit’O nto agbo Re;

Labe ibi itura.

3

Ma wi, yala l’ohun jeje

Ma je k’emi lo laigbo;

Ma wi, Oluwa, Iwo mo

Gbogbo ero okan mi,

IWO m’ohun ti mo fe

So mi di eni ’bukun.

4

Ma wi, je ki emi mura

Bi mo ba ti gb’ohun Re;

Pelu ’gboran ati ayo,

Ni ki nfi tel’oro Re

Kristi, mo teti sile

Mawi, Oluwa mawi