Hymn 455
Ki iwo ki o si ma fi won ko awon omo re nigbati iwo bajoko ninu ile re.
Meter: 8.8.8.D.
Scripture: Deut. 6:7
1
mfNigba mo joko n’ile mi,
Ki iwe Re se ’keji mi;
crKi nma f’ayo ka oro Re,
Ki nsi ma rohun ife Re
Ki nwadi oro mimo na
Titi yoo fi je temi.
2
mfJek’oro ore-ofe Re
Je kiki oro enu mi!
Be l’Oluwa yo ba mi rin,
Y’o tikare ba mi soro
Be l’okan mi yo m’oju Re,
Y’o si kun fun ’fe ailopin.
3
mfNigbati mo ba dubule,
Jeki oro ilana na
Ki o fi aya mi bale,
Ki nsimi laya Baba mi,
Ki nsun fonfon ki nsi l’ayo
Ki nsi r’iran ayeraye.
4
fKi nyin Oluwa ’gba mba ji,
Ki nkede Re l’ojo gbogbo,
Ki nje k’oro or’-ofe Re
Kun okan ati ahon mi;
crK’ife Re gba emi mi kan,
Si ka mi mo ijo t’oke.