Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 456

Ibukun nifun awon ti ngbo oro Olorun ti nwon si ona mo.

Meter: 8.,7.8.7.

Scripture: Lk. 11:28

1

mfBukun wakati na ti to

Jesu, ’gba t’a sunmo O

Lati gbo oro ’yebiye

Ti nti enu Re jade!

2

Pelu wa loni bukun wa,

Ka ma j’olugbo lasan;

Te oto Re mo wa l’aya,

Ti mbe n’nu oro iye.

3

fWo wab’a tin wa igbala,

Ti a joko l’ese Re.

A nreti ni iparoro

Lati gb’ohun didun Re.

4

mfLa wa n’iye, k’O si to wa

L’alafia l’ona orun;

F’atupa oto saju wa,

Ki a ma ba sina lo.

5

Se wa l’eni tutu, pele,

K’a ma figboya s’oto

crL’okun lo, ka ma ba kose,

Ko s’ewu ninu ’mole.

6

mfF’imole, ife, agbara

Fun oro Re lat’oke

Ko ma sise b’iwukara

Ni inu wa titi lo.

7

fRan wa lowo, ka le jeri

Si otito t’a dimu;

Ka si je k’awon elomi

To adun oto na wo.