Hymn 459
Oro Re ni fitila fun ese mi ati imole si ipa ona mi.
Meter: 7.6.7.6.D.
Scripture: OD. 119:105
1
fIWO Oro Olorun,
Ogbon at’oke wa;
Oto ti ki yipada,
Imole aye wa:
crAwa nyin O fun 'mole,
T’inu iwe mimo;
Fitila fun ese wa
Ti ntan titi aye.
2
mfOluwa l’O f’ebun yi
Fun Ijo Re l’aye,
A ngbe ’mole na soke
Lati tan y’aye ka,
Apoti wura n’ise,
O kun fun otito,
Aworun Kristi si ni,
Oro iye, loto
3
fO nfe lele b’asia
T'a ta loju ogun;
O ton b'ina alore,
Si okunkun aye;
Amonu eniyan ni,
pNi wahala gbogbo,
Nin’arin omi aye,
crO nto wa sodo Krist’.
4
fOlugbala se’jo Re
Ni fitila wura;
Lati tan Imole Re
Bi aye igbani;
KO awon ti o sako,
Lati lo’mole yi
Tit’okun aye y’o pin,
Ti won o r’oju Re.