Hymn 464
Gbogbo iwe mimo ti o ni imisi Olorun li o si ni ere fun eko.
Meter: 8.8.8.D.
Scripture: II Tim. 3:16
1
mpNipa imisi Re, l’awon
Mimo igbani k’oro Re,
B’o ti wa latetekose
Be lo wa titi d’isiyi;
Iye ti mbe n’nu oro na
JO, mi si inu Okan wa.
2
B’a ti nka Oro mimo na
Pelu adura at’ife,
Ran Emi Re lat’oke wa
Ki o le so okan wa ji;
Le gbogbo okunkun wa lo,
F’imole Or’-ofe to wa.
3
pNigbati a ba si sako,
Ti a ko Olorun sile,
JO, fi oye ese ye wa;
Ba wa wi, si mu wa pada;
Mu wa banuje f’ese wa,
Si foro Re tu wa ninu.
4
crMu wa k’eko ore ofe
Lati inu Oro iye;
Ko wa ni gbogbo ona Re,
Mu wa mo pipe ife Re
Mu gbogbo Ipinnu Re se,
So wa di okunrin pipe
5
mfPese wa fun ise rere,
Ohun-elo ta ya soto,
K’a je iranwo f’elomi
Ni ipokipo ti nwon wa,
Lati to won, lati ko won,
L’ ona iye ainipekun.