Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 465

Oro re dunju oyinlo li enu mi.

Meter: L.M.

Scripture: OD. 119:103

1

mfDidun l’Oro Re je fun mi,

Oluwa, mo ti fe won to;

Imole re ntan l’ona mi,

Ogo re ntan lat’oke wa.

2

fMo ri ayo nin’Oro na,

Ijura iyebiye ni;

Lati mo ijinle ’fe Re,

Lati ma w’ogo ite Re

3

crOgbon eniyan ko le ko,

Oye eniyan ko le mo;

Nipa imisi Re nikan

L’a fi ko iwe mimo na.

4

mpIwe iyanu n’Iwo gbe

Le awa eda Re lowo;

Awon eni-mimo ’gbani,

Nipa Emi, won kowe na.

5

fOmi iye ni f’okan wa,

Eko re nmu inu wa dun;

O nso ’gbagbo at’ife ji,

O nmu ki ipe wa daju.

6

mfIwo otito at’ife

Ti O nfona iye han wa,

F’ore-ofe fun gbogbo wa

K’a je pipe niwaju Re.