Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 466

Ki o si gbo gbogbo eyiti Oluwa Olorun wa yio wi.

Meter: 7.6.7.6.D. & Ref.

Scripture: Deut. 5:27

1

pBami soro Oluwa

Soro l’ohun jeje

Ki ngbo ohun ife Re:

“Emi wa pelu re”

Lu mi ni ookan aya

Ki nyara gbohun Re,

F’orin ’yin kun okan mi

Ki nl’ayo ninu Re

CHORUS

ppWi fun mi l’ohun jeje

Ohun ife didun,

Pe “un o ju asegun lo,

Un o bo patapata

’Jojumo ki nle ma gbo

Ohun Emi didun

Soro na fun mi loni;

“Emi wa pelu re”

2

mpWa b’awon ’mo Re soro

To won s’ona mimo,

Fi ayo kun okan won;

Fi adura ko won;

Ki won fara won rubo,

Ki won faye won ji

K’ijoba Re yarade,

K’oju wa le ri O.

3

mfSoro bi ti igbani,

Fi ife Re han wa,

Ki nmo gbogbo ise mi,

Ki nmu ase Re se;

To mi ki ngb’ogo Re ga,

Ki nfi iyin Re han,

Ki nma fayo jise Re,

Ki ngbe O ga titi.