Hymn 470
E ma wa inu iwe mimo
Meter: 11.10.11.10. & Ref
Scripture: Jn. 5:39
1
fDi Bibeli mu b’ohun miran kuna,
Ma so ilana Re to s’owo nu;
Ihin ayo Re njo okan ti ntogbe
Iye si ni ‘leri re je fun o
CHORUS
ffDi Bibeli mu! Di Bebeli mu!
Oluto, amoona lo je fun wa
2
mfDi Bibeli mu, ‘sura ‘yebiye ni;
O nf’iye anipekun f’araye;
Ko si ida na to le won iye re;
Wa ibukun re nigba to le ri
3
f‘Mole ni fun gbogbo awon asako,
Amona fun odo t’iba subu;
‘Reti f’elese t’aye re ti daru,
Opa f’ogbo iwe to dara ju.