Hymn 472
Omokunrin tujuka, a dari ese re ji o.
Meter: C.M
Scripture: Mat. 9:2
1
fJesu mi, mu mi gb’ohun Re,
S’oro alafia;
Gbogbo ipa mi y’o dalu
Lati yin ore Re.
2
pFi iyonu pe mi l’omo,
K’O si dariji mi:
Ohun na yio dunmo mi,
B’iro orin orun.
3
fIbikibi t’O to mi si,
L’emi o f’ayo lo
Tayotayo l’emi o si
Dapo m’awon oku.
4
f’Gba eru ebi ba koja,
Eru mi ko si mo;
Owo t’o fun ’dariji ka,
Y’O pin ade iye.