Hymn 473
Nipa ewo li odomokunrin yio fi mu ona re mo? Nipa ikiyesi gege bi oro re.
Meter: C.M.
Scripture: OD. 119:9
1
mfBawo ni awon ewe wa,
Y’otima soro won?
Bikose “nipa’kiyesi,
Gege bi oro Re.”
2
’Gba oro na wo’nu okan,
A tan imole ka;
Oro na ko ope l’ogbon,
At’ imo Olorun.
3
fOrun ni, imole wa ni,
Amona wa l’osan;
Fitila ti nfonahan wa,
Ninu ewu oru.
4
Oro Re oto ni titi,
Mimo ni gbogbo re:
Amona wa l’ojo ewe.
Opa l’ojo ogbo.