Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 475

La mi li oju ki emi ki o le ma wo ohun iyanu wonni lati inu ofin Re.

Meter: 8.8.9.8.8.8.8.4.

Scripture: OD. 119:18

1

mpLa mi l’oju ki mba le ri

Oro otito Re fun mi;

Fi ijinle ife Re han mi

Ti y’o SO mi di omnira;

pNi ’dakeje ni mo nduro;

Mo mura lati se ’fe Re,

La mi l’oju, mu ’mole wa

Emi Orun.

2

mfSi mi l’eti, ki mba le gbo

Ohun otito Re fun mi;

Je ki iro opo ohun Re

Tu gbogbo etan esu ka;

pNi ’dakeje ni mo nduro,

Mo mura lati se ’fe Re

Si mi l’eti, mu ’mole wa

Emi Orun.

3

mfLa mi l’ohun ki mba le so

Oro otito Re yika;

RO mi l’okan, mura mi sile

Ki nle to adun ’fe Re wo.

pNi'dakeje ni mo nduro,

Mo mura lati se 'fe Re,

Ro mi l'okan, mu 'mole wa

Emi Orun.

4

mpSi mi n’iye, ki mba le ka

Ti ife Re nin’ oro Re;

Kini y’o tun ma deruba mi

‘Gbati ‘mole Re ba nto mi;

pNi ‘dakeje ni mo nduro

Mo mure lati se’fe Re

Si mi ni ‘ye, mu mole wa,

Emi Orun

5

La ‘na sile k’emi le mu

Ebun ofe wa f’Oba mi;

N’nu ife, oro Re y’o dun ju

Orin t’awon angeli nko;

pNi ‘dakeje ni mo nduro,

Mo mura lati r’ife Re,

La ‘na sile, mu ‘mole wa,

Emi Orun