Hymn 477
Eyi ni ayanfe omo mi, Eni ti inu mi dun si gidigidi.
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: Mat. 3:17
1
mpJesu ti o gba mi la
WO ’nu odo Jordani;
O jade kuro n’nu re,
A si m’O’l’Om’Olorun,
Nipa ohun ’fe Baba,
At’iwa le adaba;
Jesu Oluto t'emi
Bi Re mo fe ’tebomi.
2
ppNin’ogba ibanuje
Bo okan Re bi omi;
Ni Kalfari l’origi
A! ni Jesu ku fun mi,
A kan mi po pelu Re;
’Reti mi ni pe O ku;
Mo ni ’po mi lese Re,
Mo njiya nitori Re.
3
pN’nu ’boji titun lo sun,
O mu eru Re kuro,
O la ’kuta re koja,
O l’ogo titi laelae;
Mo fe ka sin mi mo Krist’
Nin’ ase ta bere yi,
Bi mo si ti nyo s’oke,
Ki nwa l’otun s’Olorun.