Hymn 479
Gbogbo wa ta ti baptisi sinu Kristi Jesu a ti baptisi wa sinu iku Re.
Meter: C.M.
Scripture: Rom. 6:3
1
mfJesu, Iwo l’a gb’ohun si,
Mi Emi Mimo Re
Si awon eniyan wonyi
Baptis’ won s’iku Re
2
mpK’O fi agbara Re fun won.
Fun won l’okan titun;
Ko ’ruko Re si aya won,
Fi emi Re kun won.
3
mfJeki won ja bi ajagun
L’abe opagun Re;
Mu won f’otito d’amure,
Ki won rin l’Ona Re.
4
mpOluwa, gbin wa s’iku Re,
K’ajogun iye Re;
L’aye, ka ru agbelebu,
K’a ni ade Orun.