Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 48

E yi li ojo ti Oluwa da; awa o ma yo inu wa yo si ma dun ninu Re.

Meter: C.M

Scripture: OD 118:28

1

fEyi l’ojo t’Oluwa da,

O pe ‘gba na n’ti Re;

Korun k’o yo, k’aye ko yo

K’iyin yi ‘te na ka.

2

loni O jinde n’nu oku,

Ijoba satan ‘tu

‘Won mimo tan ‘segun Re ka

Won ns’oro ‘yanu Re.

3

ffHosana si Oba t’a yan

S’omo mimo Dafid’,

MfOluwa, jo sokale wa

T’Iwo t’igbala Re.

4

Abukun l’Oluwa t’o wa

N’ise ore-ofe

T’o wa l’oruko Baba Re,

Lati gba ran wa la.

5

ffHosana ki ohun goro,

L’orin ijo t’aye,

Orin t’oke orun l’ohun,

Yio dun ju be lo.