Hymn 487
Eyiyi li ayanfe Omo mi, eniti inu mi dun si gidigidi; e ma gbo tire.
Meter: L.M.
Scripture: Mat. 17:5
1
mfGbo ohun t’o dun lat’oke
Si Jesu l'odo Jordani,
Eri fun gbogbo araye
“Eyi l’ayanfe Omo Mi.”
2
Alailese, Eni pipe,
Sugbon nitorit’ a pase
Iwenumo ninu odo,
O f’ara Re se apere
3
Omo okan aya Baba,
Igbala fun gbogbo eda,
Orisun iye elese.
Jordani t’oke Kalfari.
4
Wa, tele Olugbala re,
Ninu ase ilo s’odo,
Apere iba Jesu ku,
Ati ajinde pelu Re.
5
fWa, ma tan idi asiri
T'o wu Oluwa lati bo,
F’igboran saju; nikehin
Ere re y’o fi ara han.