Hymn 488
Eni ti o ba gbagbo, ti a ba si baptisi re yio la; sugbon eniti ko ba gbagbo yio jebi.
Meter: 8.7.8.7.4.7.
Scripture: Mk. 16:16
1
mfWo, awon t’o wo 'so ala
Won duro leti odo,
Won k’eyin s'aye at’esu
Won ntele Atebomi;
fWon si nreti.
Lati se ase Jesu.
2
mfWo bi won ti duro l’eru,
Sugbon pelu ireti,
Won mo pe Olugbala won
L’Opase odo lilo.
fJordan’tutu,
Sugbon igbagbo gbona.
3
mfSi wo awon arakunrin
Egbon won ninu Jesu,
Wo bi won ti na 'wo ife
Won sa ti dabi won ri,
Nisisiyi,
Won ny’ayo idariji.
4
fLo tele Olugbala yin;
E f’oju igbagbo ri;
A! orun si, Emi Baba
Sinke lat’ oke wipe,
ff“Awon wonyi
Ni ayanle omo Mi.”