Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 489

On wasi baptisimu ironunpiwada fun imukuro ese.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: Lk3:3

1

mfOhun ti ndun l’aginju,

Ohun alore ni,

Gbo b’o ti ndun rara pe,

“E ronupiwada”

Ohun na ko ha dun to?

Ipe na ko kan O?,

Kil’ o se, arakunrin,

Ti o ko fi mira?

2

f“Ijoba ku si dede”

Ijoba Olorun,

Awon t'o ti fo ‘so won

Nikan ni yio gunwa

Ese t’o ko fi nani

Ohun alore yi,

Ti ndun l’eti re tantan

Pe, “Ronupiwada?”

3

mfAbana eplu Farpar;

Le je odo mimo,

Sugbon ase ‘wenumo,

Jordan’ nikan l’o ni;

Ju ero re s’apakan,

Se ase Oluwa,

Wa sinu adagun yi,

We, k’o si di mimo.

4

mfKin’ iba da o duro?

Awawi kan ko si;

W’odo, wo Johannu re,

Ohun gbogbo setan:

O pe ti o ti njiyan,

O ha ba Emi ku?

Elese, gbo alore,

Si ronupiwada