Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 49

Nitori Iwo, Oluwa li o ti mu mi yo nipa Ise re.

Meter: L.M

Scripture: OD 92:4

1

fDidun ni ‘se na, Oba mi,

Lati ma yin Oruko Re,

Lati se ‘fe Re l’owuro

Lati so oto Re l’ale.

2

pDidun l’ojo ‘simi mimo,

Lala ko si fun mi l’oni,

Okan mi ‘ba le ma korin

Bi ohun duru Dafidi!

3

pOkan mi o yo n’Oluwa,

Y’o yin ise at’oro Re

Ise ore Re ti po to!

Ijinle si ni imo Re.

4

mfEmi o yan ipo ola

‘Gb’ ore ofe ba we mi nu,

Ti ayo pupo si ba mi

Ayo mimo lat’oke wa.

5

f‘Gbana un o ri, un o gbo, un o mo

Ohun gbogbo ti mo ti nfe,

Gbogbo ipa mi y’o dalu

Lati se ife Re titi.