Hymn 490
Eje Jesu Kristi Omo Re ni nwe wa nu kuro ninu ese wa gbogbo.
Meter: 9.7.10.7. & Ref.
Scripture: IJn. 1:7
1
fAgbara mbe n’nu eje Jesu,
‘Tori o w’ese mi nu;
Mo si mo pe isin Re li ayo,
O s’okun mi di ’mole
CHORUS
ffAgbara mbe, agbara t’o sise ’yanu
Agbara mbe; agbara ti o nwe wa mo
Mbe ninu eje Jesu.
2
mfAgbara mbe n’nu eje Jesu
O gba mi LOWO ebi,
’Gbati mo k’eru ese mi to wa
Eje Re si we mi mo
3
fEmi mo ire t’eje na nje,
O ti so wa di titun
Nipa eje Re iyebiye na,
Mo di mimo titi lae.