Hymn 491
Emi li onje iye na.
Meter: L.M.
Scripture: Jn. 6:48
1
fJesu, ayo okan gbogbo,
Orisun ’ye, imole wa,
diNin’ opo bukun aye yi,
crLaini ‘telorun, at’O wa.
2
fOtito Re duro laelae
pWon gb’awon to kepe O la;
crAwon ti o wa O ri O,
fBi gbogbo nin’ohun gbogbo.
3
fA to O wo Onje Iye,
A fe jel’ara Re titi;
A mu ninu Re, Orisun,
Lati pa ongbe okan wa.
4
pOngbe Re sa ngbe okan wa
Nibikibi t’owu k’awa;
cr’Gbat’a ba ri O awa yo,
fAyo nigbat’ a gba O gbo.
5
mpJesu wa ba wa gbe titi,
Se akoko wa ni rere;
crLe okunkun ese kuro,
ffTan ’mole Re mimo s’aye.