Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 494

Eje Jesu Kristi ni nwe wa nu kuro ninu ese wa gbogbo.

Meter: 7.8.7.8.7. & Ref.

Scripture: IJn. 1:7

1

fKil’o le w’ese minu,

Ko si lehin eje Jesu;

Ki l’o tun le wo mi san,

Ko si lehin eje Jesu.

CHORUS

mpA! eje ’yebiye,

To mu mi fun bi sno

Ko s’isun miran mo.

Ko si lehin eje Jesu

2

fFun wenumo mi, nko ri

’Kan mi, lehin eje Jesu;

Ohun ti mo gbekele

Fun ’dariji, l'eje Jesu

3

pEtutu f’ese ko si,

Ko si lehin eje Jesu,

lse rere kan ko si,

Ko si lehin eje Jesu.

4

mpGbogbo igbekele mi,

Ireti mi l’eje Jesu;

Gbogbo ododo mi ni,

Eje, kiki eje Jesu.