Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 495

Fi eti si mi, Oluso-agutan Israeli, Iwo ti o nda Josefu bi owo-agutan.

Meter: 10.10.

Scripture: OD. 80:1

1

mf’Wo Oba aanu, lat’ ori ’te Re.

Fi ife wo wa, si gbo igbe wa.

2

mp“Wo Olusagutan eniyan Re,

Pa awon agbo agutan Re mo

3

pOlugbala, iku Re n’iye wa,

F’iye ainipekun fun gbogbo wa.

4

crOnje orun, Iwo ni onje wa,

Se ’ranwo okan wa nigba ’ponju;

5

p’Wol’Alabaro, Ore elese.

cr’WO n’ibu ayo wa titi laelae.

6

fWa f’ore-ofe Re mu ’nu wa dun,

Si je k’a ma ri ojurere Re.

7

mfNigba osan, ati nigba oru,

Sunmo wa, k’o s’okun wa d’imole.

8

crMa ba wa lo, k’O si ma ba wa gbe,

N’iye, n’iku, ma je itunu wa.

9

mfL’ojojumo f’oju ’fe Re to wa,

Si mu wa dele wa l’alafia.