Hymn 497
Emi o siferan Re, emi o si fi ara mi han fun U.
Meter: 10.10.10.10.
Scripture: Jn. 14:21
1
mfOluwa, mo mba O pade nihin
Igbagbo mu mi wo ohun orun
Uno fi agbara ro mo ore Re,
pUno si fi ara are mi ti O.
2
mfEmi’O je akara Olorun,
Emi o mu waini orun pelu Re,
Nihin, un o so eru aye kale,
Nihin, un o gba idariji ese
3
Emi ko ni ’ranwo mi lehin Re,
Apa re l’o to lati f’arati,
crO to wayi, Oluwa mi, o to,
Agbara mi mbe ninu ipa Re.
4
crTemi ni ese, Tire l’ododo,
crTemi l’ebi, Tire l’eje ’wenu,
mfEwu abo, on alafia mi
L’eje at’ododo Re Oluwa.
5
Gbat’ a ba dide t’a si palemo
T’a ko akara ati wain’ kuro;
Sibe IWO wa nihin, Oluwa;
Lati je orun ati asa mi.
6
diBi ase yi ti nde ti o si nlo,
crO n ran wa leti ase nla t’orun;
fO nfi ayo didun ase na han
Ase ayo, ’yawo Od’ Agutan.