Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 512

Ohun ti Olorun ba so sokan, ki enia kio mase ya won.

Meter: 7.6.7.6.D.

Scripture: Mat. 19:6

1

mfBaba, Eleda gbogbo,

Ninu ogbon Re nla;

Lo so awon meji po

Ninu ogba Eden;

fFifun awon ’mo Re yi;

Ife atorun wa,

K’ibukun wa n’ile won,

Ile t’Olorun ngbe.

2

mpN’igbeyawo Galili,

Iwo ba won pejo

Jo, sokale s’arin wa,

Bukun oko, aya;

crSo ikoro di adun,

So ekun di erin;

Ko won lati mo O li

Onise iyanu.

3

pEmi Orun alaye,

Mi si won lat’oke;

Fun won ni iwa-mimo,

Fun won n’ife pipe,

Jo, ma je amona won,

Ki won le sa fese

Se akoso aye won,

Ki won le dabi Re.

4

crB’lwo ko ko ile na,

Wuhala asan ni;

B’IWO ko si n’ile won,

Asan ni ayo won;

mfSugbon ile T’IWO wa

Idapo didun ni;

’Biti ife Re ba wa;

Ife ailopin ni.