Hymn 515
Nitori eyi li okunrin yio se fi baba ati iya re sile, on o si dapo mo aya re.
Meter: 7.7.7.D.
Scripture: Efe. 5:31
1
mfOluwa, f’ase Re si
Idapo t’a njeri yi;
F’ola Re ba wa pejo,
F’ileri ’fe won mule;
So ’dapo yi di mimo
Fun won ati lodo Re.
2
’Wo fara han ni Kana
N’igbeyawo bi eyi;
Ba wa pade nihinyi,
’Wo orisun ibukun!
Fi ayo t’aye ko ni
Se ’gbeyawo yi l’oso.
3
mfA ko fe ise ’yanu,
Pe ki omi di waini;
Gbogbo ife okan wa
Ni, k’a to ife Re wo;
K’agbara lat’oke wa
So ’fe aye di mimo.
4
mfLat’ oni lo, Oluwa,
Jek’ ajo t’oko t’aya,
B’oti le wu k’o gun to,
De opin li odo Re;
crNi ile isimi ni,
fNi ile Re li orun.