Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 517

A si pe Jesu ati awon omo ehin re pelu si ibi iyawo.

Meter: C.M.

Scripture: Jn. 2:2

1

mfN’ilu Kana ti Galili,

Nib’ ase ’gbeyawo,

Jesu fara Re han nibe,

Pel’awon ’mo-ehin.

2

pJesu masai fara Re han

Nibi ’gbeyawo yi,

K’O si fi ibukun Re fun

Oko ati aya.

3

pJeki won lewa n’irepo,

Ni ojo aye won;

K’ife at’orun wa so won,

K’aye ma le ja won.

4

pKi won ma ran ’ra won lowo

Nipa ajumose;

Fi alafia Re kun won,

Fun won n’i telorun.

5

pGege b’ire ojo kini,

Ni ogba Edeni,

Ki won ma bi, ki won ma re,

Tit’ opin emi won;