Hymn 518
A si pe Jesu ati awon omo ehin re pelu si ibi igbeyawo
Meter: C.M.
Scripture: Jn. 2:2
1
mfJesu f’ara han nitoto
Nibi ase ’yawo
Oluwa, awa be O, wa
F’ara Re han nihin.
2
Fi ibukun Re fun awon
Ti o da ’wopo yi;
F’oju rere wo ’dapo won,
Si bukun egbe won.
3
F’ebun Ife kun aya won,
Fun won nl 'telorun;
Fi alafia Re fun won,
Si busi ini won.
4
F’lfe mimo so won d’okan
Ki won f’ife Kristi
Mu aniyan ile fere;
Nipa ajumose.
5
Je ki won ran ’ra won lowo
Ninu igbagbo won;
Ki won si ni omo rere,
Ti y’o gbe ‘le won ro.