Hymn 519
IWO O dubule, orun re yio si dun.
Meter: 6.5.6.5.
Scripture: Owe. 3:24
1
mpOjo oni lo tan
Orun sunmole;
Okunkun ti de na,
Ile si ti su.
2
Okunkun bo ile,
Awon ’rawo yo;
Eranko at’eye
Lo si ’busun won.
3
mfJesu f’orun didun
F’eni alare;
pJe ki ibukun Re
Pa oju mi de.
4
crJe k’omo kekere
La ala rere;
S’oloko t’ewu nwu
Ni oju omi.
5
pMa toju alaisan
Ti ko r’orun sun;
mfAwon tinro ibi
Jo, da won l’ekun.
6
pN’nu gbogb’ ewu oru,
Te k’angeli Re
Mase olusomi
Lori ’busun mi.
7
mp’Gba’ ile ba si mo
Je k’emi dide
fB’omo ti ko l’ese
Ni iwaju Re.
8
ffOgo ni fun Baba,
Ati fun Omo,
Ati f’Emi Mimo
Lae ati laelae.