Hymn 524
E si ma ko eko lodo mi, nitori oninu tutu ati onirele okan li emi.
Meter: 7.6.8.6.
Scripture: Mat. 11:29
1
mfMo fe ki ndabi Jesu
Ninu Iwa pele;
Ko s’eni t’o gb'oro ’binu
L’enu Re lekan ri.
2
Mo fe ki ndabi Jesu
L’adura ’gba gbogbo;
pLori oke ni On nikan
Lo pade Baba Re.
3
mfMo fe ki ndabi Jesu
Emi ko ri ka pe;
Bi nwon ti korira Re to
Ko s’enikan ni ‘bi.
4
Mo fe ki ndabi Jesu
Ninu Ise rere;
K’a le wi nipa t’emi pe;
“O se ’won t’o le se.
5
Mo fe ki ndabi Jesu
T’o f’iyonu wipe,
“Je k’Omode wa s’odo mi,”
Mo fe je ipe Re.
6
pSugbon nko dabi Jesu,
O si han gbangba be;
crJesu fun mi l’ore-ofe,
Se mi, ki ndabi Re.