Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 527

A si bi Jesu ni Betlehemu ti Judea.

Meter: 8.7.8.7.7.7.

Scripture: Mat. 2:1

1

mfNigba kan ni Betlehemu,

Ile kekere kan wa,

Nib’iya kan te ’mo re si,

Lori ibuje eran;

Maria n’iya omo na,

Jesu Krist si l’omo na.

2

O t’orun wa s’ode aye,

On l’Olorun Oluwa;

O file eran se ile

’Buje eran fun ’busun;

Lodo awon otosi,

Ni Jesu gbe li aye.

3

Ni gbogbo igba ewe Re,

O ngboran, O si mb’ola;

O feran, O si nteriba,

Fun iya ti ntoju Re!

O ye ki gbogb’ omode

K’o se olugboran bo.

4

’Tori On je awose wa,

A ma dagba bi awa;

O kere ko le da nkan se,

pA ma sokun bi awa;

O si le ba wa daro,

fO le bawa yo pelu.

5

A o f’oju wa ri nikehin

Ni agbara ife Re;

Nitori omo rere yi

Ni Oluwa wa l’orun;

O nto awa omo Re

S’ona ibiti On lo.

6

fKi se ni ibuje eran

Nibiti malu njeun

L’awa o ri, sugbon l’orun

L'owo otun Olorun;

’Gba won ’mo Re b’irawo

Ba wa n’nu aso ala.