Hymn 529
Ma wi, Oluwa, nitori iranse Re n gbo.
Meter: 6.6.6.6.8.8.
Scripture: I Sam. 3:9
1
mf‘Gbati Samuel’ ji
To gbo ohun Eleda
Ni gbolohun kokan,
Ayo re ti po to!
Ibukun ni f’omo t’o ri
Olorun nitosi re be.
2
B’Olorun ba pe mi
Pe, On li Ore mi;
Ayo mi y’o ti to,
Un o si f’eti sile;
Un o sa f’ese t’o kere ju
B’Olorun sunmo ‘tosi be.
3
Ko ha nba ni soro?
Beni, n’nu oro Re
O n pe mi lati wa
Olorun Samuel,
N’nu Iwe na ni mo ka pe
Olorun Samuel npe mi.
4
Mo le l’ori pamo
S'abe itoju Re;
Mo mo p’Olorun mbe,
L'odo mi n ‘gbagbogbo;
O ye k’eru ese ba mi
N’tor’Olorun sunmo ’tosi.
5
‘Gba mba nka oro Re,
Ki nwi ni Samuel pe
"Ma wi, Oluwa mi
Emi y’o gbo Tire”
’Gba mo ba si wa nile Re,
Ma wi, ’tori ’ranse Re ngbo.