Hymn 530
Nitori ibi hiha li enu ona na ati toro loju ona na ti o lo si ibi iye
Meter: C.M.
Scripture: Mat. 7:14
1
mfOna kan lo ntoka s’orun
Isina ni ’yoku
Hiha si l’oju ona na,
Awon Kristian lo fe.
2
Lat’ aye o lo tarata
O si la ewu lo;
crAwon ti nfi ’gboya rin in,
Y’o d’orun nikehin.
3
mfAwon ewe yo ha ti se
Le la ewu yi ja;
’Tori idekun po l'ona
F’awon odomode.
4
pGbigboro l’ona t’opo nrin
O si teju pelu
Mo si mo pe lati d’ese
Ni won se nrin nibe.
5
mfSugbon kese mi ma ba ye
Ki nma si sako lo;
Oluwa jo s’oluto mi,
Emi ki o sina.
6
Nje mo le lo laisi ’ foya
Ki ngbekel’ oro Re
pApa Re y’o s’agutan Re
Y’O si ko won dele.
7
crBeni uno la ewu yi ja
Nipa itoju Re;
fUn o tejumo ’bode orun
Titi uno fi wole.