Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 531

Nwon ti fo aso igunwa won nwon si so won di funfun ninu eje Odo-agutan.

Meter: C.M. & Ref.

Scripture: Ifi. 7:14

1

fYika or’ite Olorun

Egberun ewe wa;

Ewe t’a dari ese ji.

Awon egbe mimo.

CHORUS

Nkorin Ogo, ogo, ogo.

2

Wo olukuluku won wo

Aso ala mimo;

Ninu imole ailopin

At’ ayo ti ki sa.

3

mfKi l’o mu won de aye na,

Orun t’o se mimo;

crNib’ alafia at’ayo,

Bi won ti se de be.

4

pNitori Jesu ta ’ je Re

Lati k’ese won lo;

A ri won ninu eje na,

Won di mimo laulau.

5

mfL’aye won wa Olugbala,

Won fe oruko Re;

crNisisiyi won r’oju Re,

Won wa niwaju Re.

6

pOrisun na ha nsan loni?

Jesu mu wa de be;

K’a le ri awon mimo na,

K’a si ba won yin O.