Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 537

Kojuja si ese, on a si sa kuro lodo nyin

Meter: 6.5.6.5.

Scripture: Jak. 4:7

1

mfMase huwa ese

Ma soro ‘binu;

Omo Jesu l’e se

Omo Oluwa.

2

mfKrist’ je Oninure,

At’ Eni Mimo;

Be l’awon omo Re

Ye k’o je mimo.

3

pEmi ibi kan wa

T’o nso irin re;

O si nfe dan o wo

Lati se ibi.

4

E ma se gbo tire,

B’o ti le soro

Lati ba esu ja

Lati se rere.

5

mfEyin ti se ‘leri

Ni omo owo;

Lati k’esu sile

Ati ona re.

6

Om’ ogun Krist’ niyin,

E ki lati ba

Ese inu yin ja,

E ma se rere.

7

fJesu l’Oluwa yin,

crO se Eni re;

Ki eyin omo Re

Si ma se rere.