Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 542

E je ki awon omo kekere wa Sodo mi

Meter: 6.7.8.6.8.1.1.

Scripture: Lk. 18:16

1

mf’Gba ’won iya Salem

Gb’omo won to Jesu wa;

Awon om’ehin Re le won

Wipe ki won ma lo,

Sugbon ki won to ma salo

CHORUS

fKrist ri won, O f’ayo wipe; Je ki awon omo wewe to Mi wa.

fWon y’o ba mi gbe ’nu ogo, Je ki awon omo-wewe to Mi wa.

mpNibit’ Olugbala so pe; Je ki awon omo-wewe to Mi wa,

fFarahan b’Olorun ife, Ko awon 'mo wewe lati to O wa.

2

mpEm’ o tewogba won,

Un o gbe won mora pelu;

Emi y’o je Oluso won,

E mase le won lo;

Bi won ba f’okan won fun mi,

3

mfOlugbala wa seun;

T’O tewogba ’won ’mo na;

Sugbon opo ewe mbe ti

Ko gbo Oko Re ri;

Ti won ko ka Bibeli ri,

4

crLaipe, ki keferi

Ti mbe ni gbogbo aye

M’oro Re se, ki won si ko

Orisa won danu,

Jo tan imole Re si won,