Hymn 543
E je awon omo kekere ki o wa sodo mi, E ma si se da won lekun.
Meter: 6.5.6.5.
Scripture: Mk. 10:14
1
mfJesu, t’o po logo,
Jo, deti sile;
Gbo ’yin awa ewe,
B’a ti njuba Re.
2
B’O ti je mimo to,
Olodumare,
’WO y’o teti sile
Gba t’a ba yin O.
3
pOmode l’awa je,
A ko pe sako;
Olugbala, to wa
Si ona orun.
4
crGba wa lowo ese;
SO wa lojojo;
Je k’ a le feran Re
Ko ese wa lo.
5
f’Gbat’ O ba si pe wa
S’ile wa orun;
Layo l’a o dahun pe;
Oluwa, a de!