Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 545

Jesu si pe omo kekere kan sodo Re

Meter: 1.1.1.1.

Scripture: Mat. 18:2

1

mpJesu, ’WO onirele,

Wo mi, emi omode;

JO sanu aimokan mi,

Jek’ emi wa sodo Re.

2

diMo fe k’a mu mi t’O wa;

Oluwa, mase ko mi;

F’emi omode l’aye

N’ijoba or’-ofe Re.

3

mpO wu mi ki ndabi Re;

Fun mi l’okan igboran;

’WO Alanu, Olore,

F’okan ife Re fun mi.

4

Leke gbogbo re, Jesu,

Je nma se ’fe Baba mi

Ki nma b’Emi Re n’inu

Ki nwa f’ogo Re nikan.

5

crOdagutan Olorun

’WO ni k’o j’apere mi,

Iwo tutu, ’Wo tenu;

O si ti s’omode ri.

6

mfJesu, Ore omode,

Ni owo Re ni mo wa;

Se mi gege b’O ti ri

Si ma gbe ’nu mi titi.

7

fEmi y’o fi yin Re han

Uno fi aye mi sin O,

Aye y’o si ri Kristi,

Omo mimo ninu mi.