Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 546

Jesu si wipe, “e jeki awon omo kekere wa si odo mi. Nitori ti iru won ni ijoba Olorun.” O si sure fun won.

Meter: 7.8.7.8.8.8.

Scripture: Mk. 10:14 & 16

1

mfJesu nihin l’a duro

Lati se bi IWO ti wi;

Omo yi, ni ase Re,

L’a fi bun O nisisiyi;

CHORUS

Kristi li a fun l’omo na;

'Iru won n’ijoba orun.

2

mpFun eyi a to O wa,

Gba omo yi ti a mu wa,

Je k’a r’ogo Re nihin,

Ni anu se ni omo Re;

Ma si se fi sile laelae

L’aye ati l’orun pelu.

3

crL’aya Re l’omo yi wa

Isura owon f’okan wa,

Je k’adura wa goke,

Ya ibukun Re l’ainiwon,

Si ko oruko ti a fun

Omo yi sinu’we iye.