Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 55

Ranti ojo isimi, lati ya a simimo.

Meter: S.M

Scripture: Eks. 20:8

1

fOlorun wa orun,

T’o fi ojo mefa

Da nkan gbogbo ti mbe laye

Simi n’ijo keje

2

fO pase k’a bowo

Fun ojo isimi;

Ibinu Re tobi pupo

S’awon t’o rufin yi.

3

Awon baba nla wa,

PTi ku nin ‘okunkun;

Won je ogbo aborisa

Won ko mo ofin re

4

mfAwa de Oluwa,

Gege bi ase Re;

Leyin ise ojo mefa,

Lati se ife Re.

5

mfMimo l’ojo oni,

O ye ki a simi,

K’a pejo ninu ile Re,

K’a gbo ‘ro mimo Re.

6

Isimi nla kan ku

F’awon eniyan Re;

Om’ Olorun, Alabukun

Mu wa de simi Re!