Hymn 554
Ranti ojo isimi lati ya si mimo
Meter: L.M.
Scripture: Eks. 20:8
1
mfL eyin ’jo mefa t’ o sise,
O simi ni ijo keje,
O pase fun wa k’ a se be,
Ki a si pa OJO na mo.
2
A wa lati m’ase na se,
Ninu ile Re yi loni,
Niwon ’gbat’ a mbe nihinyi,
Jek’a mo p’O mbe lodo wa.
3
pBi ao ti s’ iwe mimo Re,
Jek’ ale ka pelu ’rele,
K’a le mo pe ’Wo l’o nsoro,
Ki ateti si eko Re.
4
Tumo re fun wa fun’ra Re
Alailogbon sa li awa,
Oro Re sa jinle pupo,
Oye wa ko si to fun u.
5
pPelu awon oluko wa,
Fi Emi Mimo Re fun won,
Ki O ma ko won n’itumo,
B’o ti wu k’ijinle na to.
6
Nigbat’ a ba kuro nihin,
Jo masai pelu ona wa,
K’a le ma se iranti Re
Titi ojo’simi miran.