Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 555

Nigbana li eni-buburu ni wa, a si mu eyi ti a fun si aiya re kuro.

Meter: 10.10.

Scripture: Mat. 13:19

1

mfJesu Oba, a pari eko wa,

Ma jeki Esu sa je l’okan wa.

2

pJesu Oba, a s’ope l’owo Re

T’O ti fun wa li onje Orun je.

3

Jesu Oba, ko s’eko bi Tire.

Ihin Re dun pupo li eti wa.

4

Jesu Oba, IWO li ao ma wo,

O ti ko wa be ninu Oro Re.

5

pJesu Oba, n’ijade wa lo yi,

A be O k’O dabobo gbogbo wa.

6

Jesu Oba, ninu gbogb’ ose yi,

pSO wa, si mu wa ri ose ti mbo.