Hymn 558
Kiyesii, awon omo ni ini Oluwa: omo inu si li ere re.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: OD. 127:3
1
mfGb’ adura wa Oluwa,
fF’ awon omo t’ O fun wa,
Pin won ninu ’bukun Re.
Si fun won l’ayo l’orun.
2
Jek’ okan won Sunmo O,
Nigba won wa l’omode
Je ki won f’ogo Re han,
L’akoko ’gba ewe won.
3
pFi eje Olugbala,
We okan won mo toto;
Je k’a tun gbogbo won bi,
Ki won si le je Tire.
4
pAnu yi l’a mbebe fun,
K’ O si gbo adura wa;
IWO l’agb’ okan wa le,
Ni anu gb’ adura wa.