Hymn 56

Mo si gbo bi enipe ohun opolopo eniyan ati bi iron omi pupo, ati bi iro ara nlanla, nwipe, Aleluya nitori Oluwa Olorun wa, Olodumare njoba.

Meter: 8.7.8.7.D

Scripture: Ifi 19:6

1

fGbogb’ogun orun nro keke,

EAngeli mu harpu won,

Awon mimo nt’ohun won se,

Lati josin t’o l’ogo;

Ojo ‘simi t’Olorun de

Ojo t’o l’ogo julo,

Orun kun fun iho ayo

A! b’isin won ti dun to.

2

fJek’a pelu awon t’orun,

Yin Olorun Oba wa;

Jek’a pa ‘le okan wa mo,

K’a f’ohun mimo korin

Apere ni ti wa le je

T’isimi ti won loke

Titi ao fi ri Oluwa

Ti a nsi l’ojukoju

3

mfK’o to d’igba na, e jeki

A ma sin l’ojo keje,

K’a f’aniyan wa s’apakan

K’a pe sinu ile Re;

O ti pase k’a ma se be,

Y’o bukun ipejo wa,

E je k’a sin li aisare

Ere re y’o je tiwa